BUKATA TÓ NBẸ LORI ỌKÙNRIN:

1. Àwọn NEPA tí muwe iná wa o
2. E ra búrẹ́dì tí ẹ bá ń darí bo wálé o
3. E ra ẹyin bo o
4. Afẹ́fẹ́ gaasi tí tan ó
5. Epo karosini tí tan o
6a. Generator tí dase sile o
6b. E ra epo bentiro sínú generator bí ẹ bá ti nbo o
7. Taya ese moto tí lọ ilẹ̀, a sana si, kò dáhùn rárá
8. Awon omo ilé ìwé máa wọlé lose to nbo
9. Owo ti tàn lórí DStv/GOtv
10. Àwọn olode tí wá bere owó o
11. Oṣù tí parí, láti sanwó tisa to nko àwọn ọmọ nílé o
12. Se e o gbàgbé pe Biscuit ati Happy Hour Ó sì mo?
13. Wọn ò máa fejo àwọn ọmọ sún ẹ, bí ó ṣe ń wọlé
14. Bàbá onile ó ní je ko gbadun
15. Ìyàwó a tún jí owó kò lapo rẹ bí ó bá nwe
16. Wọn a ní ọmọ ngbona bí ẹni pé olùtọ́jú aláìsàn ni e...
17a. E ra owó sórí ago ipe mi
17b. E ra onka Ìtàkùn ayélujára data fún mi
18. Wọn ò ní gbagb Suya, ẹja aro àti bebelo ni igba miran lale
19. Èrò amounje tutu, ayonu iloso, faanu àti bebelo dá ise ile, wàhálà tún de..
20. Àwọn ọmọ ni àwọn fe lo pápá isere ó nínú olide ranpe
21. Èlò wá là npa tí wàhálà pò tó yii..
22. Wọn ní kí ẹ dawo ebi
23. Inawo nílé àná, ìyàwó ó jé kò gbadun
24. Àwọn àbúrò àti molebi náà tún gbé bukata bo lorun
25. Kò to ronú àti paro aṣọ àti bàtà tiẹ̀.

Edumare bá wà bukun gbogbo ọkùnrin to nse ojuse!